“Iro nla; mi o salo ibi kokan, Ilu Olominira Benin ni mo wa pelu Sunday Igboho” -Ojongbon Banji Akintoye


Agba oje ninu ijijangbara fun Ominira orile ede Yoruba kuro lara Naijiria, Ojogbon Banji Akintoye ti so pe iro lasan ni aheso oro kan to n ja rain-rain wipe oun ti juba ehoro latari bi ijoba apapo se n pe’ro lati fi owo sinkun mu un.
Gege bi atejade kan ti amugbalegbe Purofeso Akintoye, iyen Maxwell Adeleye fi s’ode l’ojo aje ose yi,o ni oun n se aduroti fun Oloye Sunday Adeyemo iyen Sunday Igboho ni ilu Kutonu, wipe ni logan ti oun ba ti setan nibe, oun yoo dari pada wa s’orile ede Naijiria.
Ti eo ba gbagbe, Sunday Igboho ni owo awon agbofinro ilu Benin te, laipe yi wipe o gbe awon igbese kan to lodi si ofin Orile ede ohun. Won si ti gbe ejo re lo si ile ejo kan ni ilu na.
Akintoye so wipe: “Mi o ti gbe igbese kokan ti o lodi s’ofin ilu Naijiria.Bibere fun Ominira orile-ede Yoruba kii se ese labe ofin. Koda, ofin Naijiria ati gbogbo agbaye f’aye gba wipe eto-omoniyan ni lati gbe iru igbese be.
“Odu ni mi, ko si ibikan ti mo n salo. Asaaju ijijangbara fun Orile ede Yoruba ti gbogbo aye mo ni mo je.Koda, mo sese se agbejade iwe kan lori oro n ti o je bi atona fun gbogbo awon ajijangbara to ku ni ile Yoruba.
“Ko si bo se le buru to, ko si iru ihale ti ijoba Naijiria le gbe wa, to le mu mi beru debi wipe mo wa n sa kaakiri. Lailai, ka ma ri! Ni logan ti won ba ti tu Sunday Igboho sile, mo n bo ni Naijiria. Eru kokan o ba mi. Mi o se s’ofin orile ede Naijiria.
Ojogbon Akintoye wa lo anfaani na lati se afomo oro lori Sunday Igboho. O ni aheso lasan ni wipe gbogbo ile Yoruba ti pada leyin Igboho lori ejo re to wa ni ile ejo ni Kutonu. O ni digbi l’awon nbe leyin Oloye Adeyemo.





