IROYIN

Idi re ti Awujale fi wo’gi le Ojude-Oba t’odun yi

168views

Káábíèsí Akile Ìjèbú, Alayéluwa Ọba Sikiru Adetona, Awujale ti wo’gi le ayẹyẹ àjọ̀dún ojude-Oba ti ọdún yi.

Nínú atejade kan ti ọjọgbọn, olóyè Baagbimo of Ijebu, (Dr.) Fassy Yusuf fi le’de, Kábíyèsí gbe igbese ohun latari ajakale arun COVID-19, eyi ti o tun ṣẹṣẹ gba ònà míràn yoo lakotun, láìpé yi, l’orile ede Nàìjíríà.

Ọjọgbọn Fassy ti o tún je alakoso fun ayẹyẹ àjọ̀dún ohun se afomo ọrọ wípé, Kábíyèsí o fe fi èmi àwọn èèyàn tafala, nígbà to je wipe ogunlọgọ àwọn eero ni won ma n peju si Ijebu-Ode lodoodun lati se ayajo ayeye Ojude-Oba.

O ni Kabiyesi ki gbogbo omo Ijebu lapao fun iwapẹlẹ ati àlàáfíà ti won gba laaye lati joba nilu ijebu ati agbegbe re. O wa gba awon eeyan l’amoran lati rii wipe won n tele gbogbo alaale idabobo fun arun COVID-19 nipa wiwo ibomu won daada loorekore ati lati ri wipe won o se if’aralura.

Oba Adetona tun dupelowo awon oluranwo fun Ojude-Oba lati igba de igba, -iyen awon ileese nlanla ti on se alatileyin fun ayeye ohun.

Leave a Response