IROYIN

Onilu Ayinla Omowura, Adewole Onílù-Ola jade l’aye

33views

Iku p’Abiri, Abiru ku. Iku p’Abiri, Abiri r’ọrun. Iku ti tun ti gb’ehin ja’le-ola l’agodo onilu. Iku tun ti s’ose o, iku ti pa Adewole Onílù Ola, ti o jẹ ogbontarigi Alapala ti o da Egbe akorin Ayinla Omowura sile.

Ọkan ninu ọmọ Onilu ola, Kameel lo fi iroyin ohun s’ọwọ s’ode wipe baba ohun ti di ara-ile.

Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógorún (97) ni baba Adewole nṣe ki o to t’erigbaso l’ana ode òní, ìyẹn ojo-isegun ọjọ kokandinlogbon osu Kejìlá.

Eto isinku yóò wáyé l’oni ni ile rẹ ni ilu Abeokuta.

OgunToday yóò ma mu labare bi gbogbo eto yóò ṣe lo wà fún yín lori fónrán yìí.

Leave a Response