
Ayo subu lu’dunu fun gbajugbaja olorin Fuji nni, Alhaji Wasiu Alabi Pasuma nigba to ke gbajari lori ero alatagba Instagram wipe omo oun Obirin ti o ma n fi nki ara re ninu orin nigbagbogbo, iyen Opeyemi L’america ti di jagunjagun ori-omi ni ilu Amerika lohun.
Sebi Yoruba ni inu eni kii dun ka pa a mo’ra, eyi lo mu Pasuma fi iroyin ohun le’de lori Instagram fun gbogbo agbaye lati ri.
Gegebi akoole Pasuma l’oju ewe instagram re, orisun idunu gba-a l’Opeyemi ma n je fun baba re nigba gbogbo.

E gbo bi Pasuma se ko: “Mo ki ara mi pe mo ku oriire o. Omo mi, Opeyemi L’america, iwo ku oriire. Gbogbo igba lo ma n mu inu mi ati iya re dun. Eledua a ma a to isise re ninu ise ti o yan laayo yii. Amin yah ALLAHU. E MA LO WA OOO IJOBA LAWA OOO”




