IROYIN

Awon omo Yorùbá tepele mo pipe fun òmìnira orile-ede Oduduwa

Wòròwó ni awon oluwode ya bo oju popo l'Akure

91views

Ogooro awon omo Yorùbá ni ilu Akure ni won tu yaya jade lati fi ero okan won han si ipe fun orile ede olominira Oduduwa lati da duro kuro lara orilẹ ede Naijiria.

Takotabo, tolori-telemu ni won ya bo oju popo olu-ilu ipinle Ondo loni ojo abameta, 22 Osu Ebibi.

Egbe Ilana Omo Oodua ti Purofeso Banji Akintoye n se atona fun lo so owo po pelu awon egbe miran lati se agbekale iwode alalaafia ohun.

Wòròwó si ni ohun gbogbo nlo ni ilu Akure nibi ti iwode ohun ti n ṣẹlẹ.

E wo die ninu aworan lati ibi iwode

Leave a Response