IROYIN

Boroboro l’awon odaran yii nka, nipa bi won se ge eya-ara awon eeyan kan si wele-wele. Won ni oogun-owo l’awon fe fi se

5views

Owo-sikun awon Olopaa n’ipinle Ogun ti ba awon afurasi marun ti won gbagbo wipe won l’owo ninu iku arabirin kan ati Olokada kan, iyen Memunat Akinde ati Ibikunle Ajose. Boroboro ni won nka l’akolo olopaa.

Won ni won ti jewo wipe looto l’awon gbimopo lati ji awon oloogbe mejeeji gbe, leyin eyi ti won du won pelu ada l’orun ti won si kun eya-ara won yeleyele ni ilu Badagry.

Gegebi alukoro olopaa n’ipinle Ogun, DSP Abimbola Oyeyemi ti se so f’awon oniroyin, ijoba ibile Ado-Odo/Ota ni isele ohun ti se ni Osu kewa, odun yii leyin ti awon oloogbe ohun deede poora.

DSP Oyeyemi salaye wipe owo eja tita ni Memunat ti o je eni odun marundinladoota nse ki o to di wipe o bo si owo awon ajinigbe ohun. O ni l’ojo kini, Osu kewa ni Obirin ohun lo si oja kan nitosi ile re lati ra eja ti o fe tun ta. Loju ona oja ohun ni won si ti ji oun ati olokada ti o gbee, iyen Ajose, salo.

“Oko arabirin ohun lo ke gbajare si ile-ise wa wipe iyawo oun ti sonu. Komisona olopaa n’ipinle Ogun, Edward Ajogun si pa lase fun awon olopaa ki won fi oro ohun se awari ti obirin n wa nkan-obe.” DSP Oyeyemi lo so be.

O te siwaju wipe ko pe, ko jina ni awon Olopaa to pinpin afurasi kan ti oruko re nje Okediran Monsuru lo si ilu Badagry ti owo-sikun si te e nibe.

O ni: “Mimu ti a mu Okediran, lo ran wa lowo lati ri awon elegbe re to ku mu, iyen Ajaoba Monday, Akewusola Wajud ati Nupo Pona.”

DSP Oyeyemi wa fi kun oro re pe, awon odaran ohun ti nka bi aje ti o je eepo-obo, wipe looto l’awon pa Memunat ati Ajose ni ifonna-fonsu. Won ni didu l’awon du awon eeyan ohun l’orun, ti awon si pin eya-ara won si yeleyele. Won ni Ajagungbale kan ti oruko re nje Lebo loni ki awon o se bee.

oju awon odaran na re o

Oga Olopaa ohun se l’alaye wipe looto, l’awon ba ori Memunat ati Ajose ni ojubo kan ni Badagry sugbon Lebo ti juba ehoro.

Awon odaran na tun ka wipe, leyin ti awon ti ji awon oloogbe na gbe, awon fi okun di won l’owo s’eyin ninu ile-akoku kan ni abule kan ti won n pe ni Abisoye. Won ni nigba ti Lebo de, o pa a l’ase wipe k’awon o fi ada be ori awon eeyan mejeeji na. Logan si ni Nupo Pona so ori awon oloogbe na ka’le.

Laipe ni won pe Adahunse ti o n ba won se oogun, iyen Dasu Sunday, eni ti o so fun won wipe ki won o pin eya-ara Memunat ati Ajose si yeleyele lati le ko sinu apo. Won jewo wipe Oogun owo ni Sunday fe ba Lebo se, pelu awon eya-ara ohun.

Wayi o, awon odaran mararun ohun ti wa l’akolo olopaa, sugbon Lebo ati awon to ku si ni awon olopaa si n wa kiri bayi.

Leave a Response