IROYIN

IKU D’ORO: TB Joshua t’eri gba’so l’Eko

89views

Ilumoka oniwaasu to tun je oludasile ijo Synagogue Church of All Nations ni ilu Ikotun l’Eko ti pa’poda.

Woli Temitope Joshua Balogun, ti gbogbo eeyan mo si TB Joshua lo se alaisi lorumoju aaro yi, leyi to ku bi ojo mejo ki o se ojo-ibi odun mejidinlogota lori eepe.

Gegebi afilede ti ijo Sinagogu te jade lori Facebook won, Alagba TB Joshua si se iwaasu ninu ipade kan ti won se lana, ojo satide ti won pe ni ‘Emmanuel TV Partners Meeting’. Ninu oro re to so ninu ipade ohun lo ti so pe: “igba ati asiko nbe fun gbogbo nkan. Asiko ti to wayi fun adura ati lati pada lo si ileleyin isin toni”

Ifilede ohun tun so pe “Gegebi bi oro Woli TB Joshua, ona kan to tobi ju lati gbe igbe-aye eni ni lati lo fun awon nkan ti yoo ma a fohun leyin iku oluwa re. Ise isin Woli Joshua fun imugbooro ijoba Olorun yoo ma a fohun leyin re lati iran de iran”

Ojo kejila, Osu Kefa, Odun 1963 ni a bi Woli TB Joshua. Oun lo si je oludasile ati Oludari Ijo Synagogue, Church of All Nations (SCOAN) ati Emmanuel Telifisan ti ijo ohun n se akoori re.

Leave a Response