IROYIN

“Ko si aye fun ajoyo carnival n’ipinle Ogun l’odun yii” -Gomina Abiodun

4views

Gomina Ipinle Ogun, Omo’ba Dapo Abiodun ni o ti fa’gile ajoyo opin-odun ti a mo si Carnival lolokan-o-jokan jakejado ipinle Ogun. Gomina tun so wipe gbogbo ile ijosin ti o wu lati se isin opin-ati-ibere odun, ni lati ri i daju wipe won tele gbogbo ilana ti ijoba fi le’le lori itankale aisan kokoro korona.

Ololajulo Omo’ba Abiodun tun fi kun-un wipe gbogbo awon osise ijoba ni lati lo fun isinmi keresi ati odun tuntun lati oni, ojoru, ti i se ojo kerinlelogun (24th) osu kejila titi di ojo kerin osu kini odun 2021.

Gomina ti o gba enu akowe iroyin re so’ro, -iyen Kunle Somorin, se afomo oro na wipe ki awon ara-ipinle ogun o rii daju wipe awon eeyan ti iye won o ju bi aadota lo, ni won le ko’ra jo, ti o ba dandan wipe ki won o se esin opin-odun, bi beeko, ki won gbagbe e.

Oro ohun jade leyin ti gomina Abiodun ti ba awon olori-esin ati awon adari agbegbe se ipade ni ilu Abeokuta.

Gegebi atejade ohun ti se wi: “Gbogbo ile-iwe ti o wa n’ipinle ogun ni o ni lati wa ni titi-pa titi di ojo kejidinlogun, osu kini, odun 2021. Bakanna, gbogbo ile-igbafe lolokan-o-jokan na ni lati wa ni titi pa dain-dain.

“Gbogbo oja ti o wa n’ipinle ogun ni lati ri i wipe won na oja ohun laarin agogo mejo owuro titi di agogo merin irole, lailai fi oju di gbogbo ilana ti o wa nile lori itankale kokoro korona.

Ajo ti o n m’oju to itankale arun ni orile ede naijiriya, iyen NCDC lo so wipe awon eeyan ti iye won je 80,922 ni won ti lu’gbadi aisan korona lati ijo ti o ti wo ilu Naijiriya losu keji odun 2020. Won ni awon eeyan 1,236 ni won ti gba ekuru je l’owo ebora latari aisan ohun nigbati awon eeyan 69,274 ni ori ko yo, leyin ti won ti se agbako aisan ohun.

Leave a Response