IROYIN

Boko Haram Pa Awon Fulani DaranDaran N’ipakupa; Mokandinlogun ni won ran lo s’orun Apapandodo

57views

Awon Fulani darandaran ti iye won n lo bi Ogun ni awon omo egbe Boko Haram ti yin’bon pa l’ojo Abameta to koja yi n’ilu Borno nitosi ibode Naijiria ti o sun mo Cameroun.

Awon ti oro ohun se oju won so wipe ija be sile nigba ti awon Fulani ohun yari wipe awon o ni gba mo ki awon Boko Haram ma a pa eran awon nipakupa.

Oro di isu-ata-yanayan l’Abule kan ti won n pe ni Fuhe, nigba ti awon egbe mejeeji bere si ni yinbon sira won, ti won si n p’arawon ni ipakupa.

Olori ajija-esin Jihad kan l’adugbo ohun, Umar Kachalla so f’awon oniroyin wipe mokandinlogun ni gbogbo awon Fualni darandaran ti awon egbe alatako Boko Haram pa ninu isele ohun.

Kachalla si se afikun wipe gbogbo awon oku ohun ni won ti ko si ibudo awon olopaa to wa nilu ohun.

Iroyin ti a gbo ni wipe awon Boko Haram ti gbinaya pelu awon agbe ati awon darandaran latari wipe won fura siwon gegebi alami awon olopaa ati soja.

Leave a Response