IROYIN

O n r’ugbo bo; Olota ati Alake tu’to sir’awon l’oju lori oro-Ile Gbalefa

'Ile-ejo ti fa ile na fun wa" -Alake. "Iro nla ni, awa la n'ile wa" Olota

64views

Inu-fo, Aya-fo l’awon olugbe Iju-Atan ati agbegbe re wa bayi l’atari faakaja kan to n r’ugbo bo laarin Kabiyesi, Alake ti ile Egba ati Olota ti ile Ota.

Gbogbo awon olugbe agbegbe t’oro na kan labe ijoba ibile Ado Odo/Ota ni Ajegunle, Onigbongbo, Ketu Oluyomi, Atan, Kooko ati Iju.

Idi-aba ni wipe awon Oba Alaye mejeeji n’leri lati lo gbogbo agbara won l’ori oro ile ohun. Alake l’oun l’oun n’ile ohun nigba ti Olota f’aake kori wipe awon ile na kii se t’Alake, t’oun Olota ni.

Alatan ti ilu Atan, Oba Olatunji Oluyomi ti o je kabiyesi l’abe Alake ti Egba, fi esun kan Olota ati awon Oba alaye meji miran wipe won n ja du ile ti kii se tiwon.

O ni Olota, iyen Oba (Prof) Abdulkabir Obalanlege di panpa pelu Onilogbo ti Ilogbo, iyen Oba Samuel Ojugbele lati fi ona-eru gba ile ti o je ti Egba, ti won so o di ti won.

Ninu oro re, Alatan ni Oba Oluyomi ati awon oloye Olota ni won o ti e b’esu-b’egba lati tele gbogbo ase ti ile ejo ti pa lori oro ile ohun. O ni nise ni won n jaye familete-ntuto lori oro na.

Ninu awijare re, Alatan ni ile ti oro kan yi, ni o ti je ile awon babanla awon ara Egba lati igba iwase. O ni, Alake si ni o ni agbara ati ase lori ile na.

Enu onikan la n ti n gbo ‘poun’. E gbo nkan ti Oba na so: “Olota ati awon emewa re kan n te ofin l’oju mo’le ni. Awon omo ajagungbale ni won n lo lati gba ile ti o je ajogunba ti wa, -iyen awa Egba. A ti ko iwe lorisirisi si Ijoba lori oro na, a si ti fi to awon olopa l’eti.

“Idajo marun otooto lo ti fi idi re mule wipe Olota ko ni ase kankan l’ori oro Gbalefa, -Iyen ile na. Sugbon Kabiyesi Olota, Oba Onilogbo ati Oniko o beru ofin, -won se bi eni wipe ko si ofin to le mu won.

“Oba Adedotun Aremu Gbadebo, iyen Kabiyesi Alake ti ile Egba nikan lo l’ase lori ile Gbalefa ati agbegbe re. Itan ati aroba si fi’idi oro yi mu’le daada. Fun apeere, Baale meedogbon otooto ati oloye meje ni Alake ti fi je ni Gbalefa ti a n soro re yi, laisi wahala kankan. Gbogbowon ni won si n be l’abe Kabiyesi Alake.

“Ota ki i se Gbalefa. Won yato si ara won, bo tile je wipe abe ijoba ibile Ado-Odo/Ota kanna ni awon mejeeji wa. Won jo p’aala ni, won kii ikankanna”

Ninu oro tire, Olota ti ilu Ota, Oba (Prof) Abdulkabir Obalanlege so wipe jibiti lasan l’oro ile ti won n pe ni Gbalefa. O ni ko si nkan to jo be.

O se ikilo fun Alake ati awon emewa re wipe ki won so’ra se l’ori oro ile ti ki i se tiwon. O fi kun wipe, ko si itan kankan to fi idi re mule be.

Oro kabiyesi re e: “E je ki n se afomo ror yi daju. Emi ati awon eeyan mi o ni ja lori ile kankan ti kii se tiwa. Ohun ti o ba fi mu ki omo Ota ba enikeni ja l’ori oro ile, a je wipe ile ohun t’Ota ni!

“Awon agbofinro paapa mo si oro na. mo si fe ki won sise won daada.” Olota lo se afikun oro re bee.

O ni ti o ba da Alake ati awon emewa re loju, ki won o mu idajo ile-ejo ti o pase pe ki won gba ile na, jade si gbangba.

Leave a Response