IROYIN

Osere Tiata, Dagunro jade l’aye

415views

Ogbontarigi osere ori itage, Fasasi Olabankewin, ti gbogbo aye mo si “Dagunro Alakija Oogun”, ti jade laye.

Iroyin ti o nte iko OgunToday l’owo fi ye wa wipe, Dagunro je ipe Eledua ni kutukutu owuro oni (iyen ojo Alamisi).

Awon ti o sun mo oloogbe ohun so wipe, alagba Bankewin ti n ba aisan kan ti won o daruko ja lati bi odun die seyin ki o to di wipe olojo de.

Akowe egbe osere TAMPAN ti Ipinle Osun, Ademola Adedokun, ti o se afomo iroyin iku oloogbe ohun so wipe ilu eko ni Dagunro dake si.

O ni won yoo sinku re nirole oni nilu Osogbo.

Leave a Response