IROYIN

Egbe LP fun Ile Igbimo Asofin ni Gbendeke Ojo Meje Pere lati yi Ipinu re pada lori oro awon alaga ibile ti won fe yo l’oye

322views

Egbe oselu Labour (LP) n’Ipinle Ogun ti b’enu ate lu bi ile igbimo asofin Ipinle Ogun se ja’we lo joko-je le awon alaga ijoba ibile kaakiri ipinle yi, l’owo.

Egbe Labour si fun awon asofin ohun ni gbendeke ojo meje pere lati yi ipinu na pada, l’eye-o-soka.

Alaga egbe oselu ohun n’ipinle yi, Abayomi Arabambi so wipe igbese ohun ti se afihan irufe ijoba ti gomina tuntun, Omoba Dapo Abiodun yoo je.

O ni ipinu ohun lo to’ka wipe alatako ominira ijoba ibile ponbele ni gomina Abiodun je.
Arabambi wa ke si Aare Muhammadu Buhari ati awon alokoso egebe All Progressives Congress (APC) lati tete da aso bo omoye, ko to di wipe omoye rin-hoho w’oja.

Ninun oro re, alaga egbe LP so wipe: “Bi irufe nkan bayi ba ti e n sele l’awon ibomi l’orile-ede yi, ko ye ko je Ipinle Ogun, nibi to je wipe olaju ati omowe ni wa, ti a si ni awon asaaju ti a le to’ka si gege bi awokose gidi ninu oro oselu awarawa.”

O se afikun oro re siwaju: “Sugbon sa o, a fe fi da awon ti oro na kan wipe, ao ni dake titi ti a fi ba oro ohun de’bi to ni itumo. O si da wa l’oju wipe omoluabi ponbele ni gomina wa nse”

“Wayi o, ti gomina Abiodun ba ko to fi aake k’ori, ao gbe oro ohun lo si ile-ejo leyin ti gbendeke ojo meje ohun ba pe.”

3 Comments

Leave a Response