“Bi e o ba jawo lori oro Amotekun, e le padanu anfaani lati je aare lodun 2023” -Miyetti Allah lo so be f’awon gomina Yoruba


Egbe awon darandaran ti a mo si Miyetti Allah Kautal Hore ti se ikilo fun awon gomina Ile Yoruba wipe bi won a ba deyin lori oro Amotekun, o se e se ki iha iwo-orun Naijiriya o padanu anfaani lati je aare orile ede yi l’odun 2023.
Bi e o ba gbagbe, awon gomina mefeefa ile Yoruba ni won korapo lati da egbe ojulalakan-fi-n-sori ti a mo si Amotekun sile, lati se iranwo fun awon Olopaa lori eto aabo ile Yoruba lapapo. Bi o tile je wipe opolopo awon ara-ilu ni won lu awon gomina na l’ogo-enu, Ijoba apaapo so wipe eto ohun ko ba ofin mu.
Akowe-gbogboogbo f’egbe darandaran ohun, Alhassan Saleh nigba ti o n ba akoroyin kan lati ile-ise iwe-iroyin Punch s’oro, se atenumo wipe igbese awon gomina ohun je ohun ijakule gba a f’egbe Miyetti Allah.
E ka eda-oro re ti so ni Geesi: “Irinse Oselu gba a ni egbe Amotekun ti awon gomina Yoruba da sile. Ki i se ona abayo kokan fun eto aabo to m’ehe lorile ede yi. Nkan ti awon gomina ohun i ba ti se ni wipe, won ba teramo pipe fun idasile olopaa ipinle l’abe ofin. Nibo ni won ti fe ri owo ti won fe fi se eto Amotekun ohun nigba to je wipe opolopo won o r’owohori nipa sisan owo-osu osise deede”
“I ba san fun won ki won o jawo l’apon ti o yo lori oro Amotekun yi, bii be ko, o le se akoba nla fun Ile Yoruba lati de ipo aare l’odun 2023.” Saleh lo so be.
Egbe Miyetti Allah tun te siwaju lati gbe oriyin fun amofin agba yanyan ati minisita f’oro idajo ni Naijiriya, Abubakar Malami lori bi o ti bu enu-ate lu Amotekun, wipe ko ba ofin mu.
Saleh te siwaju, o ni: “O te wa lorun bi Malami se f’enu oro na jona wipe Amotekun o ba ofin mu. Koda, inu wa dun gan lori oro ohun, o kan je wipe o pe Malami die ko to so oro ohun”



