IROYIN

Amosun pinnu lati se atunko ile Ayinla Omowura

204views

Yoruba bo, won ni, ediye o ni ku, ka ko eyin re danu. Idi aba ree ti Ijoba ipinle Ogun fi se ipinu ati ikede wipe awon yoo tun ile Oloogbe ogbontarigi olorin apala, iyen Eegunmogaji Ayinla Waidi Omowura ko laipe yi.

Alaforolo-agba si gomina Ibikunle Amosun lori oro igbafe ati asa, arabirin Yewande Amusan lo se ikede yi l’ose to koja nigba ti o n se abewo si ile Omowura ti o wa ni Itoko, l’Abeokuta. Abewo ohun waye lati se isami odun kokandinlogi ti Eegunmogaji ti fi ile bo’ra.

Arabirin Amusan so wipe bi o tile je wipe o ku feerefe ki ijoba gomina Amosun o ko’gba wole, gbogbo ipa ni awon yoo sa lati rii wipe atunko ile Omowura pari ki o to di ojo kokandinlogbon, osu ti a wa yi, nigbati Omooba Dapo Abiodun yoo gun ori aleefa gege bi gomina tuntun.

O ni atunse ohun ni yoo so ile Omowura di ibi ikosi ohun itan (iyen Museum) fun orin apala ati ohun gbogbo ti o ni se pelu ogbontarigi olorin apala na ti o se ribiribi nipa gbigbe eya orin ohun l’aruge nigba aye re.

Bi e o ba gbagbe, laipe yi ni ijoba ipinle ogun se atunko agboole ologbe olorin afro beats, Fela Anikulapo Kuti ti o wa ni Abeokuta ti won so ibe di ibi ikosi ohun itan (iyen Museum) nipa ebi Kuti.

Nigba ti o n soro tire, omo oloogbe Omowura, Alhaja Alimot Ayinla Omowura gbe oriyin fun ijoba ipinle ogun fun ipinu won lati bu iyi fun baba re.

O ni kii wa se iyi fun baba oun nikan ni igbese na je o, yoo tun pese ise fun odo ati wipe yoo je onfa fun awon aririn-afe (tourists) si ipinle ogun.

O dupe gidigidi lowo ijoba ipinle ogun, o si gbaa l’adura wipe ajose ti o wa laarin ebi na ati ijoba ko ni baje.

Odun 1933 ni a bi Oloogbe ogbontarigi olorin apala, iyen Eegunmogaji Ayinla Waidi Omowura si ilu Abeokuta. Ojo kefa, osu karun-un, odun 1980 ni o jade laye leyin ede-aiyede kan, nibi ti won ti gun ni akunfo-igo. Won gbee dugbadugba lo si ile iwosan, sugbon ki won to gbee de Ijaiye General Hospital, l’Abeokuta, eleru sunko, elemi gbaa, Omowura si di eni-ile ti i ba ebora jeun.

Leave a Response