IROYIN

Owo Olopa ti ba awon a-fura-si ti won kolu Imeko/Afon l’ose to koja

559views

Awon Olopaa ti se afihan awon darandaran merin ti won fura si gege bi odaran agbebon ti won kolu awon agbegbe kan ni ijobe ibile Imeko/Afon.

Oruko awon merin ohun ni: Abubakar Umar, Momo Mohammed, Lawal Aliyu ati Abubakar Muhammed ti komisona olopaa ipinle Ogun, Bashir Makama so wipe won wa laarin awon darandaran agbebon ti iye won n lo si bi igba, ti won yabo Oke-Agbede, Moriwi ati Wasinmi-Okuta l’ose to koja.

Komisona Makama so wipe eeyan meji, -iyen Kabiru Ogunrinde (omo odun mejidinlogbon) ati  Segun Fakorede (omo ogbon-odun) lo padanu emi won ninu isele ohun. O tun fi kun oro re wipe awon olode meji lati ile olominira ti Benin ni awon agbebon ohun tun pa.

Bakanna l’awon olopa kan f’ara gbogbe ninu isele ohun.

Gege bi komisona na se so, awon orisirisi nkan-ija ni won ba lara awon odaran-afurasi ti won se afihan won. Nkan-ija bii ada, obe, ida ati oogun abenu-gango ni won ka mo won lowo.

Leave a Response