Kokumo: Ope o! Omo Iyabo-Oko ni Iya oun o ku mo o

0
768
Advertisement

Agba osere tiata nni, ti Eledua fun lebun ere sise pupo, iyen Sidikat Odukanwi, ti gbogbo aye mo si IyaboOko, ni omo re, Bisi Aisha ti kede wipe ko ku mo, leyin ti o ti se ikede lori ero ayelujare Instagram re wipe Iya oun ti ku, ni ojo Weneside ana.

Laaro ojoru Weneside l’Aisha kede lori Instagram wipe Iyabo Oko ti t’eri gbaso. O ni: “Iya mi ti lo. Sunre o, Iya. Sunre o”. Be e gege ni Aisha se se ikede ohun lori fonran Instagram re.

Sugbon nigba ti yoo fi di aaro ojo alamisi Tooside ni Aisha yi kanna tun se ikede wipe Iyabo Oko o ku mo o. O ni iya oun ti gbe apa soke nibi ti won gbe si, leyin ti won i ro wipe o ti ku.

Osere titata mi, Foluke Daramola-Salako si f’idi oro na mule.Oso wipe oun ti gbo l’enu omo iyabo oko wipe iya na si mbe laaye. E gbo bo ti wi: “Mo sese gbo lati enu omo IyaboOko wipe iya na ti n gb’owo re soke,wipe iya oun o ku mo. Aleluya, o wa laaye”.

O ti to bi ojo-meta kan ti aisan kan ti gbe Iyabo Oko sanle ti won si ti n gbe kaakakiri fun itoju. Ni nkan bi osu kesan odun to koja ni won dede kede wipe Iya na ti ta teeru nipa sugbon leyi ti won tun so wipe, oro o ri be mo.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here