IROYIN

Osupa ti farahan, Aawe Ramadan yoo bere l’ola, ojo-aje

374views

Iroyin ti o n to iko-OgunToday l’owo fi han wipe, awon alase esin musulumi ti fi oju ganni osupa, eyi ti o s’apeere wipe osu ramadan ti wole de.

Akowe agba fun ajo ti o n moju to nkan ti o ni se pelu oro musulumi ni Naijiriya, iyen NSCIA, Alagba Isaq Oloyede so wipe laipe Sultan ti ilu Sokoto, Saad Abubakar yoo se ikede ohun l’ale yi fun gbogbo musulumi ile Naijiriya.

Fun idi eyi, ki gbogbo Musulumi mura sile lati ki irun Aasamu lale oni, leyin eyi ti aawe ramadan yoo bere laaro ola, ojo kefa osu karun, odun 2019.

Leave a Response