IROYIN

Aare Buhari bale gude s’Abuja, leyin ojo-mewa ni ile Geesi

230views

Aare orile ede yi, Ajagunfeyinti Muhammadu Buhari ti pada si olu-ilu Naijiriya, l’Abuja leyin ojo mewaa ti o ti rin irn ajo aladani lo si ile Geesi.

Aago mefa koja ogun iseju geerege ni baalu aare bale si papako ofurufu ti Nnamdi Azikiwe International airport ni Abuja.

L’ojo keedogbon osu to koja ni Aare Buhari te’ko leti lati lo si ile Geesi fun “irinajo aladani” lai so pato nkan ti oun fe lo se.

Oro na si di ariyanjiyan laarin awon omo orile-ede yi, de bi wipe awon kan ti e gbagbo wipe ayewao ilera ara re lo d’ogbon lo se ni ilu oba.

Sugbon sa o, baba oun ti pada de silu Abuja

Leave a Response