IROYIN

“Fadeyi o ku o, Iro nla ni” -Manija re lo so be

564views

Manija ogbontarigi osere ori itage, Ojo Arowosafe ti gbogb aye mo si Fadeyi Oloro ti se afomo iroyin kan ti o n ja ranyin-ranyin wipe Fadeyi Oloro ti ku.

Manija re so wipe iro nla gba’a ni o, nkankan o se oloro o. O ni iroyin-eleje ponbele ni iroyin ohun.

Ti e o ba gbagbe, iroyin kan lo la’le jade lose to koja wipe Fadeyi Oloro ti di eni ti n ba ebora je, latari aisan kindirin ti o n ba a finra.

Sugbon manija Fadeyi so wipe

“Emi ati Fadeyi la si jo wa papo n’irole ana. Koda, nigba ti mo n lo, o pa mi lese da, ko to di wipe oun paapa pada lo sinu ile re. Iro nla gba’a n’iroyin iku re”

Iyawo Fadeyi gan paapa kin manija re leyin. O so wipe, Oko oun ko ku o

“Iro ni won pa o. Oloro o ku o,” Alhaja ti o je iyawo Fadeyi lo so be.

Ti eo ba gbagbe, laipe yi ni won so wipe ara Fadeyi Oloro ko ya, wipe o se aare gidigidi, o si wa ni ile iwosan ijoba kan l’ekoo.

Won ni aisan kindinrin ni o n ba Oloro finra

1 Comment

  1. YOU ARE FULL OF NONSENSE!!! Send Melania
    your wife first, the porno star back to her country and
    and find yourself in Germany where u originate from!!
    U r sick!@ginothesaint @edmnangagwa @matigary @JonesMusara @gundwenation @nicolehondo @nickmangwana …

Leave a Response