IROYIN

Liverpool se Barcelona jatijati, ni Messi ba n wo, bi eni to so’wonu.

397views

Iya o to’ya, a f’ada pa’kun. Ikun salo, ada sonu.

Owe yi lo se akawe irufe iya ti egbe agbaboolu Barcelona ri he l’owo akegbe won ti ile Geesi, iyen Liverpool lasale oni.

Ami ayo merin dondo ni Liverpool fi fi agba han egbe agbaboolu ti ogbontarigi elese-ayo omo Argentina, -Lionel Messi je balogun won.

Ere boolu ohun to waye ni papaisere Anfield, lo je ipele ti o kangun si agbakeyin idije European Champions League ti odun yi.

Gbogbo idan ti Lionel Messi pa pata lori odan lo ja si pabo.

Leave a Response