OmiTeyinWo’gbinL’enu: Oye Olubadan le ma bo s’owo Lekan Balogun mo o. Idi re

0
1174
Advertisement

O se e se ko je wipe eni ti gbogbo aye ti l’ero wipe oun ni yoo je oye Olubadan tuntun, iyen alagba Lekan Balogun ni ko ni de ori apere ohun o.

Be e ba gbagbe, Ojo k’eji odun yi ni Olubadan ana, Oba Saliu Adetunji w’aja ti o si je wipe Oloye Balogun tii se Otun Olubadan lo kan lati di Olubadan gegebi isedale ilu Ibadan.

Sugbon, nkan o fi be s’enure fun Balogun mo o, latari awuyewuye ti o n ja rainrain wipe ijoba ipinle Oyo ti se tan lati ma ja ewe-oye le alagba Balogun lori.

Idi-aba ni wipe, Otun Olubadan ohun ti fi igba kan ta’pa si isedale ilu ti o tun fe je Olubadan le lori leyin ti o ti ledi-apopo pelu gomina ana, Abiola Ajimobi lati fi isedale ohun wo’le tuurutu latari bi o se gba lati de ade gegebi Oba ti Gomina Ajimobi fi gbogbo awon oloye Olubadan je l’odun 2017. Eyi lodi patapata gba-a si isedale Ibadan.

Oro ohun da wahala sile gan nigba na debi wipe, won se be gbe ejo ohun lo s’ile-ejo. Lekan Balogun ati awon oloye yooku si faake-kori wipe dandan ni wipe ki ile-ejo fi onte le wipe awon ti di Oba.

Sugbon ni ile Yoruba, eeyan kii je oye Oba lemeeji otooto.

Wayi o, eni to ti f’igba kan je agbejoro agba ati komisona fun eto-idajo n’ipinle Oyo ri, Micheal Lana ti sin gomina Seyi Makinde ni gbere ipako lati ri daju wipe ko ja ewe-oye le alagba Lekan Balogun lori gegebi Olubadan.

Gomina ana, Abiola Ajimobi ati okan ninu awon Oba ti o de l’ade

O LE WU O LATI KA IROYIN YII NA : E w’oju baba ti oye Olubadan yi kan bayi

Amofin agba Lana so wipe, bi gomina ba fi be e fi Lekan Balogun j’oye Olubandan, a je wipe gomina Makinde ti ta’pa s’ofin orile ede yi, nitori wipe ejo ohun si m be n’ile ejo.

Bi oro ohun ba se be e di ooto wipe, Lekan balogun o j’oye Olubadan, a je wipe Gomina ana, Rsidi Ladoja ni yoo g’ori apere ohun.

Looto, Osi Olubadan ni Ladoja, ti o si je wipe leyin Balogun Olubadan, Owolabi Olakulehin ni o to si lori ate awon oloye Olubadan, sugbon latari wipe agbo’le kana ni Olakulehin ati Oba Olubadan to w’aja ti jade wa, oye ohun ko tun le pada si agbo’le ohun mo ni sisentele.

Oro ohun si ti wa di nkan ti awon eeyan n s’enu wuyewuye so labe iyewu won kaakiri ilu Ibadan lowolowo yi. Sebi Yoruba so wipe ‘aseele l’abowaba’, owe ohun lo dabi eni wipe, o se akoja gbogbo oro ohun

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here