“O to iye bi eedegbeta eeyan ti iko-egbe pa l’odun 2020” -Ajo WHO

0
578
Advertisement

Ajo ti o n moju to eto ilera l’agbaye, iyen World Health Organisation (WHO) so wipe o to iwon 549,000 awon omo bibi ile adulawo ti aisan iko-egbe lu pa l’odun 2020 nikan.

Ajo WHO se afikun wipe awon ti setan lati dekun aisan na laipe. Won ni awon ijoba orile-ede adulawo gbodo mura lati koju aisan ohun de bi wipe won yoo din ku ni iwon ogorin ninu ogorun nigba ti yoo fi di odun 2030.

WHO wa gb’oriyin fun awon orile-ede bii Botswana, Cabo Verde, Eswatini, Ethiopia, Kenya, Namibia, South Africa ati Togo fun akitiyan won lati dekun aisan iko-egbe.

Ajo ohun so wipe iko-egbe je aisan to pa awon eeyan ju HIV lo, ni ile adulawo

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here