Lori oro Olori Ooni to ja’we fun Kaabiyesi, Elebuibon ni o di dandan ki Olori Silekunola o se awon etutu kookan

Elebuibon ni ko fi be si babara ninu k’olori o ko kaabiyesi sugbon...

0
433

Ogbontarigi Babalawo to gbo’fa yanranyanran, to tun je Araba ti ilu osogbo, iyen Baba Yemi Elebuibon ti se afomo oro wipe Olori-k’olori to ba ko jade kuro laafin, to si se be ja’we fun Oonirisa, iyen Arole Oodua ni lati se awon etutu kookan ko ti di wipe o fe Okunrin miran. Baba Elebuibon so wipe o di dandan ki iru olori be se oro ti yoo gbe oye yeyeluwa kuro lori re.

Baba na tun se afikun wipe, ko si babara Kankan ninu wipe obirin ko kabiyesi sile sugbon, iru obirin be ko kan le ko jade gegebi obirin lasan.

Be o ba gbagbe, laipe yi la ri ka lori fonran ayelujara Instagram to kangun si Olori Silekunola Naomi, iyen Olori Ooni Adeyeye Ogunwusi ti ile-ife, nibi ti obirin ohun ti n kede wipe oun o se Olori oba mo. Bi o ti je wipe, aafin Oonirisa paapa ti so wipe, awon o le fi idi re mule ni tooto boya Olori Silekunola ti ja’we fun Kabiyesi tabi be ko.

Nigba ti o n dahun ibeere awon oniroyin, Babalawo to tun je Oluko ifafiti ati onkowe nni, Elebuibon so wipe asa Yoruba ko faramo ikosile okunrin ati Obirin sugbon ti o ba ti waye, papa julo laarin Oba-alade ati olori re, o ni awon igbese kan ti o ye ki won o gbe, nitori lati ojo ti obirin ohun ti gba lati fe Kabiyesi lo ti kuro l’obirin lasan.

E gbo bi baba na ti so: “Obiribn to ba ko ooni sile o kan le kuro lasan beeyen ko si gba ile-oko miran lo. O gbudo se awon etutu kookan ko ti di wipe yoo fe okunrin miran. O ni lati koko pada di eeyan lasan na, ki o to le gbe iru igbese bee

“Ninu asa ati ise isedale Yoruba, eewo ponbele ni ki Okunrin mii o gun ori aya’ba debi ti yoo ba ni ajosepo.

Elebuibon ni ko fi be si babara ninu k’olori o ko kaabiyesi sugbon, o ni ‘ara ile lo mo ni amodi, were lara ode ma an pe’,

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here