Bi a ti n soro yi, omo odun mejilelogbon kan ti won n pe ni Biodun Adebiyi lo ti wa latimole awon olopa, leyin ti o ti lu omo ogbon-odu, omo Hausa kan ti won npe ni Mukaila Adamu lori ariyanjiyan senji N50 owo siga ti Biodun ra.
Alupamoku ni Biodun lu Mukaila titi ti emi fi bo lara re.
Alukooro ile-ise Olopa ipinle-Ogun DSP Abimbola Oyeyemi ti o f’idi isele ohun mule lo so wipe baba Mukaila lo mu ejo ohun wa sodo olopa n’idiroko, ti o fi je ki owo sinku tete te Biodun.
Gegebi o ti se so, Baba Mukaila ni nkan bi aago mewa asale ni Biodun lo ka Mukila mo Soobu re ti o si n beere senji Aadota naira (N50) owo siga ti Biodun ra saaju asiko ohun.
Oro ohun lo mu ariyanjiyan wa, debi wipe Biodun ki Mukaila mole ti o si n lu ni ilu baara. Ilu alupamoku yi, lo mu ki Mukaila o daku ti won si gbe e digbadigba lo si ile iwosan. Sugbon, ki o to de ile iwosan, eleru sungi, aso o b’omoye mo. Mukaila ti jade laye.