Oko ajagbe-ejo kan ti te ọmọkùnrin kan pa ni òpópónà marose Eko-si-Ibadan, ti o si tun se awon meta miran lese yanna-yanna. Agbegbe ile-epo Enyol ni isele buruku ohun ti se.
Gegebi agbẹnusọ iko eso ojupopo n’ipinle Ogun (TRACE), iyen Babatunde Akinbiyi se fi to awon akoroyin leti, oko ayokele pupa kan ti o ni nomba ‘EKY 885 XP’ ati Àjàgbé-ejo al’awo dudu kan ti nomba re je ‘RSH 791 XD’, ni won kolu’ra won ti jamba ohun fi sele.
Akinbiyi so wipe ere asapajude dereba Àjàgbé-ejo lo se okunfa ijamba ohun, gegebi awon t’oro soju won se sọ.
O ni eyin oko ohun si ni ọmọkùnrin ologbe ohun ti jabo lori ere
Akinbiyi se afikun wipe won ti gbe gbogbo awon to farapa lo si ile-iwosan Olowora fun itọju