Kabiyesi, Soun ti ilu Ogbomoso Oba Jimoh Oyewumi (Ajagungbade 1) ti w’aja leyin odun mejidinlaadota (48) ti won ti wa lori apere. Ojo kerilelogun osu kewa odun 1973 ni won ja’we oye le baba na lori
Oru Satide mojumo Sunday ni baba jade láye ni nkan bii aago kan koja iseju meedogbon. Gegebi iroyin ti a gbo, kabiyesi ti n se aisan, o to ojo melo kan, ki olojo o to de. Eni odun mejidinlogorun ni baba n se kólojo o to de