E w’oju baba ti oye Olubadan yi kan bayi

0
836
Advertisement

Gege bi isedale ilu Ibadan, oye Olubadan kii se ti idile kan ni pato bi won ti ma n se ni awon ilu Yoruba yooku. Tito ni awon Oloye n to, ti won o si ma sun geregere titi ti won o fi de ipo Olubadan.

Wayi o, nigba ti Oba Saliu Adetunji ti wa s’ise gege bi Olubadan kokanlelogoji, o ti dandan ki eni ti o kangun si ori apere ohun, ko gun ori-oye gegebi Olubadan kejilelogoji.

Ninu ate oloye Olubadan, otun Olubadan, iyen alagba Lekan Balogun ni oye ohun yi kan lowowo bayi.

Be e ba gbagbe, oloye Lekan Balogun wa lara awon oloye Ibadan ti gomina ana n’ipinle Oyo, Abiola Ajimobi gbe ade le lori gegebi Oba, leyi to da ikunsinu sile laarin Olubadan ati awon oloye re.

Sineto nigba kan ri ni oloye Lekan Balogun, o si kekogboye ninu imo isakoso ati eto oro-aje ni Columbus International University, Brunel University ati Manchester University, ni Orile ede Geesi.

Lekan Balogun ti fi igba kan je Alakoso eka agbodegbeyo (PR) ti ile ise elepo Shell Petroleum Development Company. Alagba ohun si ti fi igba kan je okan ninu awon adari iwe-iroyin Triumph Newspaper, ni ilu Kano. Bakanna lo tun je olootu iwe iroyin -“The Nigerian Pathfinder” nigba kan ri. Lekan Balogun tun ti sise ri gege bi oniwadi ni ile-eko giga Ahmadu Bello University, Zaria.

L’agbo oselu, Oloye Lekan Balogun ti f’igba kan dijedupo aare orile ede Naijiriya labe egbe oselu Social Democratic Party (SDP), be e lo si ti dupo gomina ri n’ipinle oyo lati inu egbe Peoples Democratic Party (PDP). Baba na si ti je oye Sineto ri pelu.

Onkowe ati onimimo ni Oloye Lekan Balogun. Die ninu awon iwe re ni: A Review of Nigeria’s 4 years’ Development Plan, 1970-1974; Nigeria: Social Justice or Doom; Power for Sale: ti won te jade ninu iwe iroyin Punch; Arrogance of Power; Nigeria: The people must decide, ati be be lo.

Olubadan to w’aja ati awon oloye re

Ate Oloye Olubadan ati ipo ti won wa

1) Lekan Balogun: Otun Olubadan.

2) Owolabi Olakulehin: Balogun Olubada‎n

3) ‎Rashidi Ladoja: Osi Olubadan.

4). Olufemi Olaifa: Otun Balogun.

5) ‎Eddy Oyewole: Ashipa Olubadan.

6) Tajudeen Ajibola: Osi Balogun.

7) Amidu Ajibade:Ekaarun Olubadan.

8) Lateef Gbadamosi: Ashipa Balogun Olubadan.

9) Kola Adegbola: Ekarun Balogun‎.

10) Abiodun Kola-Daisi: Ekerin Olubadan‎.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here