O se e se ki owo awon olopa ti te gbajugbaja osere tita nni, Damola Olatunji leyin ti o fi esun kan awon agbofinro wipe won se amugbalegbe ohun bi o ti to; oni iwa ibaje gba a ni awon olopa na hu. Koda, o se e se ko je wipe Damola si n be l’atimole awon Olopaa bi e se n ka iroyi yii lowo.
Saaju mimu ti won mu un, Osere sinima ohun fi atejade kan sori ero ayelujara Instagram nibi ti o ti fi oju awon olopaa ohun han, pelu afikun wipe won gba foonu awon lowo won ni Abule-Egba nibi ti isele ohun ti se. O ni tipa-tikuuku ni won fi gba foonu ohun lowo ohun ati amugbalegbe re.
Koda, Damola tun se afikun wipe nise l’awon olopa ohun n gba owo-kobe lowo awon eeyan to wa ni agbegbe Abule Egba.
Ago-olopa to wa ni Area P ni Damola so wipe won mu ohun lo.