“Abẹrẹ-ajesara lásán o le ko orilẹ-èdè kankan yo nínú laasigbo Omikuronu” -Ajo WHO lo sọ bẹẹ

0
2251
Advertisement

Ajo to n mojuto ètò ilera l’agbaye, ìyẹn World Health Organisation (WHO) lo ti n kọminu wípé eya korona-fairosi ti wọn n pe Omikuronu (Omicron) ti di arank’aye ti oòrùn n ran, latari bi o se je wipe orilẹ èdè ti iye wọn n lo bi ogorun ni àìsàn ohun ti tan de káàkiri àgbáyé. orilẹ èdè wa, Naijiriya pàápàá wa nínú àwọn orile èdè ti won ti f’ara kaasa Omikuronu.

Olùdarí WHo, Dókítà Tedros Adhanom Ghebreyesus lom ke gbajare ohun láìpé yi nínú ìpàdé ti o se pèlú àwọn oníròyìn ni ìlú Geneva. Ghebreyesus se ìkìlọ wipe ki ẹnikẹni ma fi ojú rena eya COVID-19 yi o. O ni ata kéré, lo fi n soko ojú.

E gbọ bo ti wi: “Eya Omikuronu kii se eya COVID-19 to ye ka fi sere rara o. Koda, owo ti o fi n tan kaakiri agbaye ti kuro ni keremi. Ao ti ri iru eya yi ri. O si je nkan ti o n kan lominu wipe awon eeyan o mu lokukudun.

“Bi o ba ti e je wipe eya yi kii se eya to buru to be ju be lo, sugbon iye awon to ti dagunle je nkan ti o lewu, eyi ti o si le se akoba fun eto ilera, paapa julo lawon orile ede ti eto-ilera won o muno-doko [bii ti naijiriya]

“E wo, e je ki n fi da yin loju wipe abere ajesara nikan ko le ko orile-ede kankan yo ninu laasigbo Omikuronu yi. Nkan to ye ki a se ni lati dena titan-kale eya COVID-19 yi. Ona abayo kan to wa niyen” Ghebreyesus lo n ke gbonmo-gbonmo be.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here